Skip to content
1 Kronika 29:6-14

1 Kronika 29:6-14

6
Nígbà náà àwọn aṣáájú àwọn ìdílé, àwọn ìjòyè àwọn ẹ̀yà Israẹli, àwọn alákòóso ẹgbẹgbẹ̀wàá àti alákòóso ọ̀rọ̀ọ̀rún àti àwọn oníṣẹ́ tí ó wà ní ìdí iṣẹ́ ọba ní ìfẹ́ sí i.
7
Wọ́n fi sílẹ̀ fún iṣẹ́ lórí ilé Ọlọ́run, ẹgbẹ̀rún márùn-ún (5,000) tálẹ́ǹtì àti ẹgbẹ̀rin mẹ́wàá (10,000) wúrà, ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá (10,000) tálẹ́ǹtì fàdákà, ẹgbàá mẹ́sàn (18,000) tálẹ́ǹtì idẹ àti ọgọ́rin ẹgbẹ̀rin (100,000) tálẹ́ǹtì irin.
8
Ẹnikẹ́ni tí ó ní òkúta iyebíye fi wọn sí ilé ìṣúra ilé Olúwa ní abẹ́ ìtọ́jú Jehieli ará Gerṣoni.
9
Àwọn ènìyàn láyọ̀ nínú ìṣesí àtọkànwá fi sílẹ̀ àwọn olórí wọn, nítorí tí wọ́n ti fi sílẹ̀ ní ọ̀fẹ́ pẹ̀lú gbogbo ọkàn sí Olúwa. Dafidi ọba pẹ̀lú yọ̀ gidigidi.
10
Dafidi yin Olúwa níwájú gbogbo àwọn tí ó péjọ, wí pé, “Ìyìn ni fún Ọ, Olúwa, Ọlọ́run baba a wa Israẹli, láé àti láéláé.
11
Tìrẹ Olúwa ni títóbi àti agbára pẹ̀lú ìyìn àti ọláńlá àti dídán, nítorí tí gbogbo nǹkan ní ọ̀run àti ayé jẹ́ tìrẹ. Tìrẹ Olúwa ni ìjọba; a gbé ọ ga gẹ́gẹ́ bí orí lórí ohun gbogbo.
12
Ọlá àti ọ̀wọ̀ wá láti ọ̀dọ̀ Rẹ; ìwọ ni alákòóso gbogbo nǹkan. Ní ọwọ́ rẹ ni ipá àti agbára wà láti gbéga àti láti fi agbára fún ohun gbogbo.
13
Nísinsin yìí, Ọlọ́run wa, àwa fi ọpẹ́ fún Ọ, a sì fi ìyìn fún orúkọ rẹ̀ tí ó lógo.
14
“Ṣùgbọ́n ta ni èmi, àti ta ni àwọn ènìyàn mi, tí a fi lè ṣe ìrànlọ́wọ́ tinútinú bí irú èyí? Gbogbo nǹkan wá láti ọ̀dọ̀ rẹ ní ti wá, àwa sì ti fífún ọ láti ara ohun tí ó wá láti ọwọ́ rẹ.
Settings

Reading style

Typeface

Font size 19px

Reading width 75 chars

Options