Skip to content
1 Kronika 29:20-25

1 Kronika 29:20-25

20
Dafidi sì sọ fún gbogbo ìjọ ènìyàn pé, “Nísinsin yìí, ẹ fi ìyìn fún Olúwa Ọlọ́run yín.” Gbogbo ènìyàn sì fi ìyìn fún Olúwa Ọlọ́run àwọn baba wọn, wọ́n sì tẹ orí wọn ba, wọ́n wólẹ̀ fún Olúwa àti ọba.
21
Ni ọjọ́ kejì, wọ́n rú ẹbọ sí Olúwa, wọ́n sì rú ẹbọ sísun sí i: ẹgbẹ̀rún (1,000) kan akọ màlúù, ẹgbẹ̀rin (1,000) kan àgbò, àti ẹgbẹ̀rin kan akọ ọ̀dọ́-àgùntàn. Lápapọ̀ pẹ̀lú ọrẹ mímu àti àwọn ẹbọ mìíràn ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ fún gbogbo Israẹli.
22
Wọ́n jẹ wọ́n sì mu pẹ̀lú ayọ̀ kíkún ní iwájú Olúwa ní ọjọ́ náà. Nígbà náà wọ́n yan Solomoni ọmọ Dafidi gẹ́gẹ́ bí ọba lẹ́ẹ̀kejì wọ́n fi àmì òróró yàn án níwájú Olúwa láti ṣe olórí àti Sadoku láti ṣe àlùfáà.
23
Bẹ́ẹ̀ ni Solomoni jókòó lórí ìtẹ́ Olúwa gẹ́gẹ́ bí ọba ní ipò baba a rẹ̀ Dafidi. O ṣe àṣeyọrí, gbogbo Israẹli sì gbọ́rọ̀ sí i lẹ́nu.
24
Gbogbo àwọn ìjòyè àti àwọn ọkùnrin alágbára, pẹ̀lú gbogbo àwọn ọmọ ọba Dafidi tẹrí ara wọn ba fún ọba Solomoni.
25
Olúwa gbé Solomoni ga púpọ̀ ní ojú gbogbo Israẹli, ó sì kẹ́ ẹ ní ìkẹ́ ọláńlá, ní irú èyí tí a kò kẹ́ ọba kankan ṣáájú rẹ̀ tí ó jẹ lórí Israẹli.
Settings

Reading Style

Typeface

Font Size 19px

Options