1 Kronika 27:25-31
25
Asmafeti ọmọ Adieli wà ní ìdí ilé ìṣúra ti ọba. Jonatani ọmọ Ussiah wà ní ìdí ilé ìṣúra ní iwájú agbègbè nínú àwọn ìlú, àwọn ìletò àti àwọn ilé ìṣọ́.
26
Esri ọmọ Kelubu wà ní ìdí àwọn òṣìṣẹ́ lórí pápá, tí wọ́n ń ko ilẹ̀ náà.
27
Ṣimei ará Ramoti wà ní ìdí àwọn ọgbà àjàrà. Sabdi ará Sifmi wà ní ìdí mímú jáde ti èso àjàrà fún ọpọ́n ńlá tí a ń fi ọ̀tún èso àjàrà sí.
28
Baali-Hanani ará Gederi wà ní ìdí olifi àti àwọn igi sikamore ní apá ìhà ìwọ̀-oòrùn àwọn ní ẹ̀ṣẹ̀ pẹ̀tẹ́lẹ̀. Joaṣi wà ní ìdí fífún ni ní òróró olifi.
29
Ṣitrai ará Ṣaroni wà ní ìdí fífi ọwọ́ ẹran jẹ oko ní Ṣaroni. Ṣafati ọmọ Adlai wà ní ìdí àwọn ọ̀wọ́ ẹran ní àwọn pẹ̀tẹ́lẹ̀.
30
Obili ará Iṣmaeli wà ní ìdí àwọn ìbákasẹ. Jehdeiah ará Meronoti wà ní ìdí àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́.
31
Jasisi ará Hagari wà ní ìdí àwọn agbo ẹran. Gbogbo wọ̀nyí ni àwọn oníṣẹ́ tí wọ́n wà ní ìdí ẹrù ọba Dafidi.
Settings