Saamu120
Listen to this chapter
0:00
0:00
Kígbe Fún Ìgbàlà
1
Orin fún ìgòkè. Èmi ké pe Olúwa nínú ìpọ́njú mi, ó sì dá mi lóhùn.
2
Gbà mí, Olúwa, kúrò lọ́wọ́ ètè èké àti lọ́wọ́ ahọ́n ẹ̀tàn.
Àyànmọ́ Àwọn Alẹ́gàn
3
Kí ni kí a fi fún ọ? Àti kí ni kí a túnṣe fún ọ, ìwọ ahọ́n ẹ̀tàn?
4
Òun yóò bá ọ wí pẹ̀lú ọfà mímú ológun, pẹ̀lú ẹ̀yín iná igi ìgbálẹ̀.
Ẹkún Nítorí Ìgbèkùn Lábẹ́ Àwọn Aláìgbọ́ràn
5
Ègbé ni fún mi tí èmi ṣe àtìpó ní Meṣeki, nítorí èmi gbé nínú àgọ́ ìlú Kedari!
6
Ó ti pẹ́ tí èmi ti ń gbé láàrín àwọn tí ó kórìíra àlàáfíà.
7
Ènìyàn àlàáfíà ni mí; ṣùgbọ́n nígbà tí mo bá sọ̀rọ̀, ogun ni dúró fun wọn.
Use ← → arrow keys to navigate
Settings
Reading Style
Typeface
Font Size px
Reading Width chars
Options
Study Note