Skip to content

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Tirshatha

4 ẹsẹ · 1 abala

Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì

  1. Baálẹ̀ pa á láṣẹ fún wọn pé wọn kò gbọdọ̀ jẹ nínú oúnjẹ mímọ́ jùlọ títí tí àlùfáà kan yóò fi ṣiṣẹ́ ìránṣẹ́ pẹ̀lú Urimu àti Tumimu.

  2. Baálẹ̀ sọ fún wọn nítorí náà pé wọn kò gbọdọ̀ kópa nínú jíjẹ oúnjẹ mímọ́ títí tí àlùfáà tí yóò wá tí ń ṣiṣẹ́ ìránṣẹ́ pẹ̀lú Urimu àti Tumimu yóò fi dé.

  3. Díẹ̀ lára àwọn olórí ìdílé náà kópa nínú ṣíṣe iṣẹ́ náà. Baálẹ̀ fún ilé ìṣúra ní ẹgbẹ̀rún (1,000) dariki wúrà, àádọ́ta àwo koto àti ọ̀rìndínlẹ́gbẹ̀ta lé mẹ́wàá (530) ẹ̀wù fún àwọn àlùfáà.

  4. Nígbà náà ni Nehemiah tí ó jẹ́ baálẹ̀, Esra àlùfáà àti akọ̀wé, àti àwọn Lefi tí wọ́n ń kọ́ àwọn ènìyàn wí fún gbogbo wọn pé, “Ọjọ́ yìí jẹ́ ọjọ́ mímọ́ fún Olúwa Ọlọ́run yín. Ẹ má ṣe ṣọ̀fọ̀ tàbí sọkún,” nítorí gbogbo àwọn ènìyàn ti ń sọkún bí wọ́n ti ń tẹ́tí sí ọ̀rọ̀ inú òfin náà.