Fò sí àkóónú

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Priest: Polluted by marrying idolatrous wives

6 ẹsẹ · 4 abala

Àwọn ẹsẹ nípa Polluted by marrying idolatrous wives

  1. Lẹ́yìn ìgbà tí a ti ṣe àwọn nǹkan wọ̀nyí tán, àwọn olórí tọ̀ mí wá, wọ́n sì wí pé, “Àwọn ènìyàn Israẹli, tí ó fi mọ́ àwọn àlùfáà àti àwọn ọmọ Lefi, kò tì í ya ara wọn sọ́tọ̀ kúrò láàrín àwọn ènìyàn agbègbè tí wọ́n ń ṣe ohun ìríra bí i ti àwọn ará Kenaani, àwọn ará Hiti, àwọn ará Peresi, àwọn ará Jebusi, àwọn ará Ammoni, àwọn ará Moabu, àwọn ará Ejibiti àti ti àwọn ará Amori.

  2. Wọ́n ti fẹ́ lára àwọn ọmọbìnrin wọn fún ara wọn àti fún àwọn ọmọkùnrin wọn gẹ́gẹ́ bí aya, wọ́n ti da irú-ọmọ ìran mímọ́ pọ̀ mọ́ àwọn ènìyàn ti ó wà ní àyíká wọn. Àwọn olórí àti àwọn ìjòyè ta àwọn ènìyàn tókù yọ nínú híhu ìwà àìṣòótọ́.”

  3. Nígbà náà ni Esra dìde, ó sì fi àwọn aṣíwájú àlùfáà àti àwọn ọmọ Lefi àti gbogbo Israẹli sí abẹ́ ìbúra, láti ṣe ohun tí wọ́n dá lábàá. Wọ́n sì búra.

  4. Lára ìran àwọn àlùfáà àwọn wọ̀nyí fẹ́ àwọn obìnrin àjèjì. Nínú ìran Jeṣua ọmọ Josadaki, àti àwọn arákùnrin rẹ: Maaseiah, Elieseri, Jaribi àti Gedaliah.

  5. Gbogbo wọn ni wọ́n ṣe ìpinnu láti lé àwọn ìyàwó wọn lọ, wọ́n sì fi àgbò kan láàrín agbo ẹran lélẹ̀ fún ẹ̀bi wọn gẹ́gẹ́ bí ọrẹ ẹ̀ṣẹ̀.

  6. “Àwọn ènìyàn tókù—àwọn àlùfáà, àwọn ọmọ Lefi, àwọn aṣọ́nà, àwọn ìránṣẹ́ tẹmpili àti gbogbo àwọn tí wọ́n ya ara wọn sọ́tọ̀ kúrò lára àwọn ènìyàn àjèjì nítorí òfin Ọlọ́run, papọ̀ pẹ̀lú ìyàwó wọn, gbogbo ọmọkùnrin àti àwọn ọmọbìnrin wọn, tí òye yé