Skip to content

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Pamphylia

6 ẹsẹ · 4 abala

Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì

  1. Frigia, àti Pamfilia, Ejibiti, àti agbègbè Libia níhà Kirene; àti àwọn àtìpó Romu, àwọn Júù àti àwọn aláwọ̀ṣe Júù

  2. Nígbà tí Paulu àti àwọn tí ó wà pẹ̀lú rẹ̀ si ṣíkọ̀ ni Pafosi wọ́n wá sí Perga ni Pamfilia: Johanu sì fi wọ́n sílẹ̀, ó sì padà lọ sí Jerusalẹmu.

  3. Nígbà ti wọ́n sì là Perga kọjá, wọ́n wá sí Pisidia ní Antioku. Wọ́n sì wọ inú Sinagọgu ní ọjọ́ ìsinmi, wọ́n sì jókòó.

  4. Nígbà tí wọn sí la Pisidia já, wọ́n wá sí Pamfilia.

  5. Ṣùgbọ́n Paulu rò pé, kò yẹ láti mú un lọ pẹ̀lú wọn, ẹni tí ó fi wọn sílẹ̀ ni Pamfilia, tí kò sì bá wọn lọ sí iṣẹ́ náà.

  6. Nígbà tí a ré Òkun Kilikia àti Pamfilia kọjá, a gúnlẹ̀ sí Mira ti Likia.