Fò sí àkóónú

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Goat: Designated as one of the clean animals to be eaten

8 ẹsẹ · 4 abala

Àwọn ẹsẹ nípa Designated as one of the clean animals to be eaten

  1. Olúwa sọ fún Mose àti Aaroni pé,

  2. “Ẹ sọ fún àwọn ara Israẹli pé, ‘Nínú gbogbo ẹranko tí ń gbé lórí ilẹ̀, àwọn wọ̀nyí ni ẹ le jẹ.

  3. Gbogbo ẹranko tí pátákò ẹsẹ̀ rẹ̀ bá là tí ó sì ń jẹ àpọ̀jẹ.

  4. “ ‘Àwọn mìíràn wà tó ń jẹ àpọ̀jẹ nìkan. Àwọn mìíràn wà tó jẹ́ pé pátákò ẹsẹ̀ wọn nìkan ni ó là, ìwọ̀nyí ni ẹ kò gbọdọ̀ jẹ fún àpẹẹrẹ bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ìbákasẹ ń jẹ àpọ̀jẹ kò ya pátákò ẹsẹ̀, àìmọ́ ni èyí jẹ́.

  5. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé gara (ẹranko tí ó dàbí ehoro tí ń gbé inú àpáta) ń jẹ àpọ̀jẹ; aláìmọ́ ni èyí jẹ́ fún yín.

  6. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ehoro ń jẹ àpọ̀jẹ, ṣùgbọ́n kò ya pátákò ẹsẹ̀; aláìmọ́ ni èyí jẹ́ fún yín.

  7. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹlẹ́dẹ̀ ya pátákò ẹsẹ̀ ṣùgbọ́n kì í jẹ àpọ̀jẹ; aláìmọ́ ni èyí jẹ́ fún yín.

  8. Ẹ má ṣe jẹ ẹran wọn, ẹ kò sì gbọdọ̀ fọwọ́ kan òkú wọn. Àìmọ́ ni wọ́n jẹ́ fún yín.