Skip to content

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Forests

3 ẹsẹ · 22 abala

Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì

  1. “Nítorí náà ni kí o pàṣẹ pé kí wọn kí ó gé igi kedari Lebanoni fún mi wá. Àwọn ènìyàn mi yóò ṣiṣẹ́ pẹ̀lú tìrẹ, Èmi yóò sì san owó ọ̀yà tí ìwọ bá ránṣẹ́ fún àwọn ènìyàn rẹ. Ìwọ mọ̀ pé, a kò ní ẹnìkan nínú wa tí ó mọ bí a ti ń gé igi bí àwọn ará Sidoni.”

  2. Nígbà tí Hiramu sì gbọ́ iṣẹ́ Solomoni, inú rẹ̀ sì dùn gidigidi, ó sì wí pé, “Ògo ni fún Olúwa lónìí, nítorí tí ó ti fún Dafidi ní ọlọ́gbọ́n ọmọ láti ṣàkóso àwọn ìlú ńlá yìí.”

  3. Hiramu sì ránṣẹ́ sí Solomoni pé, “Èmi ti gbọ́ iṣẹ́ tí ìwọ rán sí mi, èmi yóò sì ṣe gbogbo èyí tí o fẹ́ ní pípèsè igi kedari àti ní ti igi firi.