Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Earthquakes: As judgments
Àwọn ẹsẹ nípa As judgments
Nítorí náà èmi yóò jẹ́ kí àwọn ọ̀run kí ó wárìrì; ayé yóò sì mì tìtì ní ibùjókòó rẹ̀ láti ọwọ́ ìbínú Olúwa àwọn ọmọ-ogun, ní ọjọ́ ìbínú gbígbóná rẹ.
Gẹ́gẹ́ bí egbin tí à ń dọdẹ rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí àgùntàn tí kò ní olùṣọ́, ọ̀kọ̀ọ̀kan yóò padà tọ àwọn ènìyàn rẹ̀ lọ, ọ̀kọ̀ọ̀kan yóò sá padà sí ilẹ̀ abínibí i rẹ̀.
Ilẹ̀ ayé ti fọ́ ilẹ̀ ayé ti fọ́ dànù, a ti mi ilẹ̀ ayé rìrìrìrì.
Ilẹ̀ ayé yí gbiri bí ọ̀mùtí, ó bì síwá sẹ́yìn bí ahéré nínú afẹ́fẹ́; ẹ̀bi ìṣọ̀tẹ̀ rẹ̀ ń pa á lẹ́rù tó bẹ́ẹ̀ tí ó fi ṣubú láìní lè dìde mọ́.