Skip to content

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Booth

6 ẹsẹ · 4 abala

Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì

  1. Ní ọjọ́ kìn-ín-ní, kí ẹ mú àṣàyàn èso láti orí igi dáradára, imọ̀ ọ̀pẹ, àti ẹ̀ka igi tó rúwé, àti igi wílò odò, kí ẹ sì máa yọ̀ níwájú Olúwa Ọlọ́run yín fún ọjọ́ méje.

  2. Ẹ ṣe èyí ní àjọ̀dún sí Olúwa fún ọjọ́ méje lọ́dọọdún. Èyí yóò jẹ́ ìlànà ayérayé fún àwọn ìran tí ń bọ̀, ẹ ṣe é ní oṣù keje.

  3. Ẹ gbé inú àgọ́ fún ọjọ́ méje. Kí gbogbo ọmọ bíbí Israẹli gbé nínú àgọ́.

  4. Kí àwọn ìran yín le mọ̀ pé mo mú kí Israẹli gbé nínú àgọ́, nígbà tí mo mú wọn jáde ní Ejibiti. Èmi ni Olúwa Ọlọ́run yín.’ ”

  5. àti kí wọn kéde ọ̀rọ̀ yìí, kí wọn sì tàn án kálẹ̀ ní gbogbo ìlú wọn àti ní Jerusalẹmu: “Ẹ jáde lọ sí ìlú olókè, kí ẹ mú àwọn ẹ̀ka inú olifi àti ẹ̀ka igi olifi igbó, àti láti inú maritili, àwọn imọ̀ ọ̀pẹ àti àwọn igi tí ó léwé dáradára wá, láti ṣe àgọ́”—gẹ́gẹ́ bí a ti kọ ọ́.

  6. Bẹ́ẹ̀ ni àwọn ènìyàn jáde lọ, wọ́n sì mú àwọn ẹ̀ka wá, wọ́n sì kọ́ àgọ́ fún ara wọn sí orí òrùlé ara wọn, ní àgbàlá wọn àti ní àgbàlá ilé Ọlọ́run àti ní ìta gbangba lẹ́gbẹ̀ẹ́ ẹnu ibodè omi àti èyí tí ó wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ ẹnu ibodè Efraimu.