Meshelemiah
A tún mọ̀ ọ́n sí: Shelemiah
Àwọn ẹsẹ tí ó mẹ́nu kan Meshelemiah
Sekariah, ọmọ Meṣelemiah jẹ́ olùtọ́jú ẹnu-ọ̀nà ní àbáwọlé sí àgọ́ ibi ìpàdé.
Àwọn ìpín tí àwọn olùtọ́jú ẹnu-ọ̀nà. Láti ìran Kora: Meṣelemiah ọmọ Kore, ọ̀kan lára àwọn ọmọ Asafu.
Meṣelemiah ní àwọn ọmọkùnrin: Sekariah àkọ́bí, Jediaeli ẹlẹ́ẹ̀kejì, Sebadiah ẹlẹ́ẹ̀kẹta, Jatnieli ẹlẹ́ẹ̀kẹrin,
Meṣelemiah ní àwọn ọmọ àti àwọn ìbátan, tí ó jẹ́ alágbára méjìdínlógún ni gbogbo wọn.
Kèké fún ẹnu-ọ̀nà ilà oòrùn bọ́ sí ọ̀dọ̀ Ṣelemiah. Nígbà náà a dá kèké fún ọmọkùnrin rẹ̀ Sekariah, ọlọ́gbọ́n onímọ̀ràn, kèké fún ẹnu-ọ̀nà àríwá sì bọ́ sí ọ̀dọ̀ rẹ̀.