Caleb
A tún mọ̀ ọ́n sí: Chelubai, Carmi
Àwọn ẹsẹ tí ó mẹ́nu kan Caleb
Àwọn ọmọ tí a bí fún Hesroni ni: Jerahmeeli, Ramu àti Kalebu.
Kalebu ọmọ Hesroni ní ọmọ láti ọ̀dọ̀ ìyàwó rẹ̀ Asuba (láti ọ̀dọ̀ Jerioti). Àwọn wọ̀nyí ni àwọn ọmọ rẹ̀: Jeṣeri, Ṣobabu àti Ardoni.
Nígbà tí Asuba sì kú, Kalebu sì fẹ́ Efrata ní aya, ẹni tí ó bí Huri fún un.
Àwọn ọmọ Kalebu arákùnrin Jerahmeeli: Meṣa àkọ́bí rẹ̀, ẹni tí ó jẹ́ baba fún Sifi, àti àwọn ọmọ rẹ̀ Meraṣa, ẹni tí ó jẹ́ baba fún Hebroni.
Ó sì bí Ṣaafu baba Madmana, Ṣefa baba Makbena àti baba Gibeah, ọmọbìnrin Kalebu sì ni Aksa.
Àwọn wọ̀nyí ni ọmọ Kalebu. Àwọn ọmọ Huri, àkọ́bí Efrata: Ṣobali baba Kiriati-Jearimu.
Àwọn ọmọ Juda: Peresi, Hesroni, Karmi, Huri àti Ṣobali.