Skip to content

Agrippa

12 ẹsẹ

Àwọn ẹsẹ tí ó mẹ́nu kan Agrippa

  1. Lẹ́yìn ọjọ́ mélòó kan, Agrippa ọba, àti Bernike sọ̀kalẹ̀ wá sì Kesarea láti kí Festu.

  2. Agrippa wí fún Festu pé, “Èmi pẹ̀lú fẹ́ láti gbọ́ ọ̀rọ̀ ọkùnrin náà tìkára mi.” Ó sì wí pé, “Ní ọ̀la ìwọ ó gbọ́ ọ.”

  3. Ní ọjọ́ kejì, tí Agrippa àti Bernike wọ ilé ẹjọ́ ti àwọn ti ẹ̀ṣọ́ púpọ̀ pẹ̀lú àwọn olórí ogun àti àwọn ènìyàn ńlá ní ìlú, Festu pàṣẹ, wọ́n sì mú Paulu jáde.

  4. Festu sì wí pé, “Agrippa ọba, àti gbogbo ẹ̀yin ènìyàn tí ó wà níhìn-ín pẹ̀lú wa, ẹ̀yin rí ọkùnrin yìí, nítorí ẹni tí gbogbo ìjọ àwọn Júù tí fi ẹ̀bẹ̀ béèrè lọ́wọ́ mi ni Jerusalẹmu àti Kesarea níhìn-ín yìí, tí wọ́n ń kígbe pé, kò yẹ fún un láti wà láààyè mọ́.

  5. Ṣùgbọ́n èmi kò ri ohun kan dájúdájú láti kọ̀wé sí olúwa mi. Nítorí náà ni mo ṣe mú un jáde wá síwájú yín, àní síwájú rẹ ọba Agrippa, kí o fi jẹ́ pé lẹ́yìn tí a ba tí ṣe ìwádìí rẹ̀, èmi yóò lè rí ohun tí èmi yóò kọ.

  6. Agrippa sì wí fún Paulu pé, “A fún ọ láààyè láti sọ tí ẹnu rẹ.” Nígbà náà ní Paulu ná ọwọ́, ó sì sọ ti ẹnu rẹ pé,

  7. “Agrippa ọba, inú èmi tìkára mi dùn nítorí tí èmi yóò wí ti ẹnu mi lónìí níwájú rẹ, ní ti gbogbo ẹ̀sùn tí àwọn Júù fi kan mi,

  8. Ìlérí èyí tí àwọn ẹ̀yà wa méjèèjìlá tí ń fi ìtara sin Ọlọ́run lọ́sàn án àti lóru tí wọ́n ń retí àti rí i gbà. Ọba Agrippa, nítorí ìrètí yìí ni àwọn Júù ṣe ń fi mi sùn.

  9. “Nítorí náà, Agrippa ọba, èmi kò ṣe àìgbọ́ràn sì ìran ọ̀run náà.

  10. Agrippa ọba, ìwọ gba àwọn wòlíì gbọ́ bí? Èmi mọ̀ pé ìwọ gbàgbọ́.”

  11. Agrippa sì wí fún Paulu pé, “Ǹjẹ́ ìwọ lérò pé ìwọ le fi àkókò díẹ̀ yìí sọ mí di Kristiani?”

  12. Agrippa sì wí fún Festu pé, “A bà dá ọkùnrin yìí sílẹ̀ bí ó bá ṣe pe kò ì tí ì fi ọ̀ràn rẹ̀ lọ Kesari.”