Skip to content
Rutu 4:7-12

Rutu 4:7-12

7
Ní ayé ìgbàanì, kí a tó le sọ wí pé ohun ìràpadà tàbí pàṣípàrọ̀ ohun ìní fi ìdí múlẹ̀ ní ilẹ̀ Israẹli, ẹnìkan ni láti yọ bàtà rẹ̀ kúrò ní ẹsẹ̀ rẹ̀ kí ó sì fi fún ẹnìkejì, ó jẹ́ òfin fún ẹni tí ó fẹ́ rà á. Nípa ṣíṣe èyí, àwọn ará Israẹli fihàn wí pé ọ̀rọ̀ náà ti fìdímúlẹ̀.
8
Nítorí náà, nígbà tí ọkùnrin náà sọ fún Boasi wí pé, “Ìwọ rà á fúnra rẹ̀,” ó yọ bàtà rẹ̀ kúrò ní ẹsẹ̀ rẹ̀.
9
Nígbà náà ni Boasi wí fún àwọn àgbàgbà àti àwọn mìíràn tí ó wà ní ibẹ̀ pé, “Gbogbo yín jẹ́ ẹlẹ́rìí mi ní òní wí pé mo ti ra ohun gbogbo tí í ṣe ti Elimeleki àti àwọn ọmọ rẹ̀ ọkùnrin méjèèjì: Maloni àti Kilioni lọ́wọ́ Naomi.
10
Ní àfikún, mo ra Rutu ará Moabu opó Maloni padà láti di aya mi. Èyí tí yóò mú kí orúkọ ọkùnrin òkú náà wà pẹ̀lú ohun ìní rẹ̀, kí ìran rẹ̀ má ba à lè parẹ́ láàrín àwọn ẹbí rẹ̀ àti ìlú rẹ̀. Ẹ̀yin ni ẹlẹ́rìí ní òní.”
11
Nígbà náà ni àwọn àgbàgbà àti àwọn ènìyàn tí ó wà ní ibẹ̀ dáhùn wí pé, “Bẹ́ẹ̀ ni, àwa ni ẹlẹ́rìí, kí Olúwa jẹ́ kí obìnrin tí ó ń bọ̀ wá sí inú ilẹ̀ rẹ dàbí Rakeli àti Lea láti ara àwọn ẹni tí gbogbo ìdílé Israẹli ti jáde wá. Kí ìwọ sì di ọlọ́rọ̀ ní ìran Efrata àti olókìkí ní ìlú Bẹtilẹhẹmu.
12
Kí Olúwa fún ọ ní ọmọ tí yóò mú ìdílé rẹ dàbí ti Peresi ọmọkùnrin tí Tamari bí fún Juda láti ipasẹ̀ ọ̀dọ́mọbìnrin yìí.”
Settings

Reading Style

Typeface

Font Size 19px

Options