Saamu 98:4-9
4
Ẹ hó ìhó ayọ̀ sí Olúwa, gbogbo ayé, ẹ bú sáyọ̀, ẹ kọrin ìyìn,
5
ẹ fi dùùrù kọrin sí Olúwa, pẹ̀lú dùùrù àti ìró ohùn orin mímọ́,
6
pẹ̀lú ìpè àti fèrè ẹ hó fún ayọ̀ níwájú Olúwa ọba.
7
Jẹ́ kí òkun kí ó hó pẹ̀lú gbogbo ohun tí ó wà nínú rẹ̀, Gbogbo ayé àti gbogbo àwọn tí ń gbé inú rẹ̀.
8
Ẹ jẹ́ kí odo kí ó ṣápẹ́, ẹ jẹ́ kí òkè kí ó kọrin pẹ̀lú ayọ̀;
9
ẹ jẹ́ kí wọn kọrin níwájú Olúwa, nítorí tí yóò wá ṣèdájọ́ ayé bẹ́ẹ̀ ni yóò ṣe ìdájọ́ àwọn orílẹ̀-èdè nínú òdodo àti àwọn ènìyàn ní àìṣègbè pẹ̀lú.
Settings