Saamu 94:16-23
16
Ta ni yóò dìde fún mi sí àwọn olùṣe búburú? Tàbí ta ni yóò dìde sí àwọn oníṣẹ́ ẹ̀ṣẹ̀ fún mi?
17
Bí kò ṣe pé Olúwa fún mi ní ìrànlọ́wọ́, èmi fẹ́rẹ̀ máa gbé ní ilẹ̀ tí ó dákẹ́.
18
Nígbà tí mo sọ pé, “Ẹsẹ̀ mi ń yọ̀”, Olúwa, ìfẹ́ rẹ̀ ni ó tì mí lẹ́yìn.
19
Nígbà tí àníyàn ńlá wà nínú mi, ìtùnú rẹ̀ mú ayọ̀ sí ọkàn mi.
20
Ìjọba ìbàjẹ́ ha lè kẹ́gbẹ́ pẹ̀lú rẹ ẹni tí ń fi òfin dì mọ́ ìwà ìkà?
21
Wọ́n kó ara wọn jọ sí olódodo wọ́n sì ń dá àwọn aláìṣẹ̀ lẹ́bi sí ikú.
22
Ṣùgbọ́n, Olúwa ti di odi alágbára mi, àti Ọlọ́run mi ni àpáta nínú ẹni tí mo ti ń gba ààbò.
23
Òun yóò san ẹ̀san ibi wọn fún wọn yóò sì pa wọ́n run nítorí búburú wọn Olúwa Ọlọ́run wa yóò pa wọ́n run.
Settings