Saamu 76:1-9
1
Fún adarí orin. Pẹ̀lú ohun èlò orin olókùn. Saamu ti Asafu. Orin. Ní Juda ni a mọ Ọlọ́run; orúkọ rẹ̀ sì lágbára ní Israẹli
2
Àgọ́ rẹ̀ wà ní Salẹmu, ibùgbé rẹ̀ ni Sioni.
3
Níbẹ̀ ni ó ṣẹ́ ọfà, asà àti àwọn idà, ohun ìjà ogun. Sela.
4
Ìwọ ni ògo àti ọlá, ju òkè ńlá ìkógun wọ̀nyí lọ.
5
A kó àwọn alágídí ọkàn ní ìkógun wọ́n sun oorun ìgbẹ̀yìn wọn; kò sí ọ̀kan nínú àwọn akọni tó lè gbé ọwọ́ rẹ̀ sókè.
6
Ní ìfibú rẹ, Ọlọ́run Jakọbu, àwọn ẹṣin àti kẹ̀kẹ́ ogun sì dùbúlẹ̀ síbẹ̀.
7
Ìwọ nìkan ni ó yẹ kí a bẹ̀rù. Ta ló lé dúró níwájú rẹ, nígbà tí ìwọ bá ń bínú?
8
Ìwọ ń ṣe ìdájọ́ láti ọ̀run, ilé ayé bẹ̀rù, ó sì dúró jẹ́ẹ́,
9
nígbà tí, ìwọ Ọlọ́run, bá dìde láti ṣe ìdájọ́, láti gba àwọn ẹni ìnilára ilẹ̀ náà. Sela.
Settings