Saamu 75:8-10
8
Ní ọwọ́ Olúwa ni ago kan wà, ọtí wáìnì náà sì pọ́n, ó kún fún àdàlú, ó fún ọtí àdàlú tí a pò mọ́ òórùn dídùn tí ó tú jáde, àwọn ènìyàn búburú ayé gbogbo mú u pátápátá.
9
Ṣùgbọ́n èmi, ó máa ròyìn rẹ títí láé; èmi ó kọrin ìyìn sí Ọlọ́run Jakọbu.
10
Èmi ó gé ìwo gbogbo ènìyàn búburú, ṣùgbọ́n ìwo àwọn olódodo ni a ó gbéga.
Settings