Skip to content
Saamu 68:14-22

Saamu 68:14-22

14
Nígbà tí Olódùmarè fọ́n àwọn ọba ká ní ilẹ̀ náà, ó dàbí òjò dídi ní Salmoni.
15
Òkè Baṣani jẹ́ òkè Ọlọ́run; òkè tí ó ní orí púpọ̀ ni òkè Baṣani.
16
Kí ló dé tí ẹ̀yin fi ń ṣe ìlara, ẹ̀yin òkè wúwo, òkè tí Ọlọ́run ti fẹ́ láti jẹ ọba níbi tí Olúwa fúnra rẹ̀ yóò máa gbé títí láé?
17
Ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá ni kẹ̀kẹ́ ogun Ọlọ́run ẹgbẹ̀rún lọ́nà ẹgbẹ̀rún; Olúwa ń bẹ láàrín wọn, ní Sinai ni ibi mímọ́ rẹ̀.
18
Ìwọ ti gòkè sí ibi gíga ìwọ ti di ìgbèkùn ní ìgbèkùn lọ; ìwọ ti gba ẹ̀bùn fún ènìyàn: nítòótọ́, fún àwọn ọlọ̀tẹ̀ pẹ̀lú, kí Olúwa Ọlọ́run lè máa bá wọn gbé.
19
Olùbùkún ni Olúwa, Ọlọ́run Olùgbàlà wa, ẹni tí ó ń fi ojoojúmọ́ gba ẹrù wa rù. Sela.
20
Ọlọ́run wa jẹ́ Ọlọ́run tó ń gbàlà àti sí Olúwa Olódùmarè ni ó ń gbà wá lọ́wọ́ ikú.
21
Ṣùgbọ́n Ọlọ́run yóò tẹ orí àwọn ọ̀tá rẹ̀, àti agbárí onírun àwọn tó ń tẹ̀síwájú nínú ẹ̀ṣẹ̀ wọn
22
Olúwa wí pé, “Èmi ó mú wọn wá láti Baṣani; èmi ó mú wọn wá láti ibú omi Òkun,
Settings

Reading style

Typeface

Font size 19px

Reading width 75 chars

Options