Saamu 59:1-5
1
Fún adarí orin. Tí ohùn orin “Má ṣe parun.” Ti Dafidi. Miktamu. Nígbà tí Saulu rán àwọn olùṣọ́ sí ilé Dafidi kí òun bá le rí i pa. Gbà mí lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá à mi, Ọlọ́run; dáàbò bò mí kúrò lọ́dọ̀ àwọn tí ó dìde sí mi.
2
Gbà mí lọ́wọ́ àwọn oníṣẹ́ búburú kí o sì gbà mí lọ́wọ́ àwọn ènìyàn tí ń pòǹgbẹ ẹ̀jẹ̀.
3
Wò ó, bí wọ́n ṣe ba ní bùba dè mí! Àwọn alágbára ń gbìmọ̀ lòdì sí mi kì í ṣe nítorí ìrékọjá mi tàbí ẹ̀ṣẹ̀ mí, Olúwa.
4
Èmi kò ṣe àìṣedéédéé kan, síbẹ̀ wọ́n sáré wọ́n ṣetán láti kọlù mí. Dìde fún ìrànlọ́wọ́ mi, kí o sì wo àìlera mi.
5
Olúwa Ọlọ́run Alágbára, Ọlọ́run Israẹli, dìde fún ara rẹ kí o sì bá àwọn orílẹ̀-èdè wí; má ṣe ṣàánú fún àwọn olùrékọjá búburú nì. Sela.
Settings