Saamu 50:16-23
16
Ṣùgbọ́n Ọlọ́run sọ fún àwọn, ènìyàn búburú: “Kí ní ẹ̀tọ́ tí o ní tí ìwọ fi ń tún àwọn ìlànà mi sọ, tàbí tí ìwọ sì ń sọ májẹ̀mú mi ní ẹnu rẹ?
17
Ìwọ kórìíra àṣẹ mi, ìwọ sì ṣá ọ̀rọ̀ mí tì sí apá kan.
18
Nígbà tí ìwọ rí olè, ìwọ dára pọ̀ mọ́ ọn, ìwọ sì da ara rẹ dé àwọn alágbèrè.
19
Ìwọ lo ẹnu rẹ fún aburú, ìwọ sì ń fi ahọ́n rẹ pète ẹ̀tàn.
20
Ní ìgbà gbogbo ìwọ ń sọ̀rọ̀ sí arákùnrin rẹ, ìwọ sì ń ba orúkọ ọmọ ìyá rẹ jẹ́.
21
Àwọn nǹkan wọ̀nyí ni ìwọ ti ṣe, mo sì dákẹ́; ìwọ rò pé mo jẹ́ irú kan náà bí ìrẹ, ṣùgbọ́n èmi yóò bá ọ wí, èmi yóò sì fi ẹ̀sùn kàn ọ́ ní ojú ara rẹ.
22
“Ǹjẹ́ ìwọ ro èyí wò, ẹ̀yin tí ó gbàgbé Ọlọ́run. Bí bẹ́ẹ̀ kọ́ èmi yóò fa yin ya pẹ́rẹpẹ̀rẹ, láìsí ẹni tí yóò gbà yin sílẹ̀.
23
Ẹni tí ó ba ní ẹbọ ọrẹ-ọpẹ́ bu ọlá fún mi; kí ó sì tún ọ̀nà rẹ̀ ṣe, kí èmi kí ó le fi ìgbàlà Ọlọ́run hàn án.”
Settings