Saamu 44:1-8
1
Fún adarí orin. Ti àwọn ọmọ Kora. Maskili. À ti fi etí wa gbọ́, Ọlọ́run; àwọn baba wa tí sọ fún wa ohun tí ìwọ ṣe ní ọjọ́ wọn, ní ọjọ́ pípẹ́ sẹ́yìn.
2
Ìwọ fi ọwọ́ rẹ lé orílẹ̀-èdè jáde, Ìwọ sì gbin àwọn baba wa; ìwọ run àwọn ènìyàn náà Ìwọ sì mú àwọn baba wa gbilẹ̀.
3
Kì í ṣe nípa idà wọn ni wọ́n gba ilẹ̀ náà, bẹ́ẹ̀ ni kì í ṣe apá wọn ní ó gbà wọ́n bí kò ṣe; ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ àti, apá rẹ; àti ìmọ́lẹ̀ ojú rẹ̀, nítorí ìwọ fẹ́ wọn.
4
Ìwọ ni ọba àti Ọlọ́run mi, ẹni tí ó pàṣẹ ìṣẹ́gun fún Jakọbu.
5
Nípasẹ̀ rẹ ni àwa ó bi àwọn ọ̀tá wa ṣubú; nípasẹ̀ orúkọ rẹ ni àwa ó tẹ àwọn ọ̀tá tí ó dìde sí wa mọ́lẹ̀,
6
èmi kì yóò gbẹ́kẹ̀lé ọrun mi, idà mi kì yóò mú ìṣẹ́gun lórí àwọn ọ̀tá wá,
7
ṣùgbọ́n ìwọ fún wa ní ìṣẹ́gun lórí àwọn ọ̀tá wa, ìwọ sì ti dójúti àwọn tí ó kórìíra wa.
8
Nínú Ọlọ́run àwa ń ṣògo ní gbogbo ọjọ́, àwa ó sì yin orúkọ rẹ títí láé. Sela.
Settings