Skip to content
Saamu 32:4-8

Saamu 32:4-8

4
Nítorí pé ni ọ̀sán àti ní òru ọwọ́ rẹ̀ wúwo sí mi lára; agbára mi gbẹ tán gẹ́gẹ́ bí ooru ẹ̀ẹ̀rùn. Sela.
5
Èmi jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ mi sí ọ àti pé èmi kò sì fi àìṣòdodo mi pamọ́. Èmi wí pé, “Èmi yóò jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ mi fún Olúwa,” ìwọ sì dárí ẹ̀bi ẹ̀ṣẹ̀ mi jì mí. Sela.
6
Nítorí náà jẹ́ kí gbogbo àwọn olódodo máa gbà àdúrà sí ọ ní ìgbà tí a lè rí ọ; nítòótọ́ nígbà tí ìṣàn omi ńlá bá ru sókè, wọn kì yóò lè dé ọ̀dọ̀ rẹ̀.
7
Ìwọ ni ibi ìpamọ́ mi; ìwọ yóò pa mí mọ́ kúrò nínú ìyọnu; ìwọ yóò fi orin ìgbàlà yí mi ka. Sela.
8
Èmi yóò kọ́ ọ, èmi yóò sì fi ẹsẹ̀ rẹ lé ọ̀nà tí ìwọ yóò rìn èmi yóò máa gbà ọ́ ní ìyànjú, èmi yóò sì máa fi ojú mi tọ́ ọ.
Settings

Reading style

Typeface

Font size 19px

Reading width 75 chars

Options