Skip to content
Saamu 31:1-8

Saamu 31:1-8

1
Fún adarí orin. Saamu ti Dafidi. Nínú rẹ̀, Olúwa ni mo ti rí ààbò; má ṣe jẹ́ kí ojú kí ó tì mí; gbà mí nínú òdodo rẹ.
2
Tẹ́ etí rẹ sí mi, gbà mí kíákíá; jẹ́ àpáta ààbò mi, jẹ́ odi alágbára láti gbà mí.
3
Ìwọ pàápàá ni àpáta àti ààbò mi, nítorí orúkọ rẹ, máa ṣe olùtọ́ mi, kí o sì ṣe amọ̀nà mi.
4
Yọ mí jáde kúrò nínú àwọ̀n tí wọ́n dẹ pamọ́ fún mi, nítorí ìwọ ni ìsádi mi.
5
Ní ọwọ́ rẹ ni mo fi ẹ̀mí mi lé; ìwọ ni o ti rà mí padà, Olúwa, Ọlọ́run òtítọ́.
6
Èmi ti kórìíra àwọn ẹni tí ń fiyèsí òrìṣà tí kò níye lórí; ṣùgbọ́n èmi gbẹ́kẹ̀lé Olúwa.
7
Èmi yóò yọ̀, inú mi yóò dùn nínú ìfẹ́ ńlá rẹ, nítorí ìwọ ti rí ìbìnújẹ́ mi ìwọ ti mọ̀ ọkàn mi nínú ìpọ́njú.
8
Pẹ̀lú, ìwọ kò sì fà mi lé àwọn ọ̀tá lọ́wọ́ ìwọ ti fi ẹsẹ̀ mi lé ibi ààyè ńlá.
Settings

Reading Style

Typeface

Font Size 19px

Options