Skip to content
Saamu 17:6-9

Ìgbẹ́kẹ̀lé nínú ààbò Ọlọ́run

Saamu 17:6-9

Ìgbẹ́kẹ̀lé nínú ààbò Ọlọ́run

6
Èmi ké pè ọ́, Ọlọ́run, nítorí tí ìwọ yóò dá mi lóhùn dẹ etí rẹ sí mi kí o sì gbọ́ àdúrà mi.
7
Fi ìṣeun ìyanu ìfẹ́ ńlá rẹ hàn ìwọ tí ó fi ọwọ́ ọ̀tún rẹ gba àwọn tí ó gbẹ́kẹ̀lé ọ là lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá tí ó dìde sí wọn.
8
Pa mí mọ́ bí ẹyin ojú rẹ; fi mí pamọ́ sí abẹ́ òjìji ìyẹ́ apá rẹ,
9
lọ́wọ́ àwọn ènìyàn búburú tí ń fóròó mi, kúrò ní ọwọ́ àwọn ọ̀tá apani tí ó yí mi ká.

See also

Where else Scripture says this.

  • Deuteronomi 32:10

    Ní aginjù ni ó ti rí i, ní aginjù níbi tí ẹranko kò sí. Ó yíká, ó sì tọ́jú rẹ̀, ó pa á mọ́ bí ẹyin ojú u rẹ̀.
    from verse 8
  • Saamu 91:4

    Òun yóò fi ìyẹ́ rẹ̀ bò mí, àti ni abẹ́ ìyẹ́ rẹ̀ ni èmi yóò ti rí ààbò; òtítọ́ rẹ̀ ni yóò ṣe ààbò àti odi mi.
    from verse 8
  • Saamu 91:1

    Ẹni tí ó gbé ibi ìkọ̀kọ̀ Ọ̀gá-ògo ni yóò sinmi ní ibi òjìji Olódùmarè.
    from verse 8
  • Òwe 7:2

    Pa òfin mi mọ́, ìwọ yóò sì yè tọ́jú ẹ̀kọ́ mi bí ẹyinlójú rẹ.
    from verse 8
  • Saamu 60:5

    Fi ọwọ́ ọ̀tún rẹ gbà wá, kí o sì ràn wá lọ́wọ́, kí a lè gba àwọn tí o fẹ́ là.
    from verse 7
  • Luku 13:34

    “Jerusalẹmu, Jerusalẹmu, ìwọ tí o pa àwọn wòlíì, tí o sì sọ òkúta lu àwọn tí a rán sí ọ pa; nígbà mélòó ni èmi ń fẹ́ ràgà bo àwọn ọmọ rẹ, bí àgbébọ̀ adìyẹ ti í ràgà bo àwọn ọmọ rẹ̀ lábẹ́ apá rẹ̀, ṣùgbọ́n ẹ̀yin kò fẹ́!
    from verse 8
  • Saamu 36:7

    Báwo ni ìṣeun ìdúró ṣinṣin ìfẹ́ rẹ ti tó! Ọlọ́run! Kí gbogbo ọmọ ènìyàn le sá sí abẹ́ òjìji ìyẹ́ rẹ.
    from verse 8
  • Sekariah 2:8

    Nítorí báyìí ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí: “Lẹ́yìn ògo rẹ̀ ni a ti rán mi sí àwọn orílẹ̀-èdè tí ń kó yin: nítorí ẹni tí ó tọ́ yin, ó tọ́ ọmọ ojú rẹ̀.
    from verse 8
  • Saamu 5:11

    Ṣùgbọ́n, jẹ́ kí gbogbo àwọn tí ó sádi ọ́ kí ó yọ̀; jẹ kí wọn máa kọrin fún ayọ̀ títí. Tan ààbò rẹ sórí wọn, àti àwọn tí ó fẹ́ràn orúkọ rẹ yóò máa yọ̀ nínú rẹ.
    from verse 7
  • Saamu 5:12

    Dájúdájú, Olúwa, ìwọ bùkún olódodo; ìwọ fi ojúrere rẹ yí wọn ká bí asà.
    from verse 7
  • Saamu 20:6

    Nísinsin yìí, èmi mọ̀ wí pé, Olúwa pa ẹni àmì òróró rẹ̀ mọ́. Yóò gbọ́ láti ọ̀run mímọ́ rẹ̀ wá pẹ̀lú agbára ìgbàlà ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀.
    from verse 7
  • Saamu 31:21

    Olùbùkún ni Olúwa, nítorí pé ó ti fi àgbà ìyanu ìfẹ́ tí ó ní sí mi hàn, nígbà tí mo wà ní ìlú tí wọ́n rọ̀gbà yíká.
    from verse 7
Settings

Reading Style

Typeface

Font Size 19px

Options