Skip to content
Saamu 144:7-15

Saamu 144:7-15

7
Na ọwọ́ rẹ sílẹ̀ láti ibi gíga; gbà mí kí o sì yọ mí nínú ewu kúrò nínú omi ńlá: kúrò lọ́wọ́ àwọn ọmọ àjèjì.
8
Ẹnu ẹni tí ó kún fún èké ẹni tí ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ jẹ́ ìrẹ́jẹ.
9
Èmi yóò kọ orin tuntun sí ọ Ọlọ́run; lára ohun èlò orin olókùn mẹ́wàá èmi yóò kọ orin sí ọ.
10
Òun ni ó fi ìgbàlà fún àwọn ọba, ẹni tí ó gba Dafidi ìránṣẹ́ rẹ̀ lọ́wọ́ idà ìpanilára. Lọ́wọ́ pípanirun.
11
Gbà mí kí o sì yọ mí nínú ewu kúrò lọ́wọ́ àwọn ọmọ àjèjì tí ẹnu wọn kún fún èké, tí ọwọ́ ọ̀tún wọn jẹ́ ọwọ́ ọ̀tún èké.
12
Kí àwọn ọmọkùnrin wa kí ó dàbí igi gbígbìn tí ó dàgbà ni ìgbà èwe wọn, àti ọmọbìnrin wa yóò dàbí òpó ilé tí a ṣe ọ̀nà sí bí àfarawé ààfin.
13
Àká wa yóò kún pẹ̀lú gbogbo onírúurú oúnjẹ àgùntàn wa yóò pọ̀ si ní ẹgbẹ̀rún, ní ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá ní oko wa:
14
àwọn màlúù wa yóò ru ẹrù wúwo kí ó má sí ìkọlù, kí ó má sí ìkólọ sí ìgbèkùn, kí ó má sí i igbe ìpọ́njú ní ìgboro wa.
15
Ìbùkún ni fún àwọn ènìyàn náà tí ó wà ní irú ipò bẹ́ẹ̀, ìbùkún ni fún àwọn ènìyàn náà, tí ẹni tí Ọlọ́run Olúwa ń ṣe.
Settings

Reading Style

Typeface

Font Size 19px

Options