Saamu 132:1-10
1
Orin fún ìgòkè. Olúwa, rántí Dafidi nínú gbogbo ìpọ́njú rẹ̀.
2
Ẹni tí ó ti búra fún Olúwa, tí ó sì ṣe ìlérí fún alágbára Jakọbu pé.
3
Nítòótọ́, èmi kì yóò wọ inú àgọ́ ilé mi lọ, bẹ́ẹ̀ èmi kì yóò gun orí àkéte mi.
4
Èmi kì yóò fi oorun fún ojú mi, tàbí òògbé fún ìpéǹpéjú mi,
5
títí èmi ó fi rí ibi fún Olúwa, ibùjókòó fún alágbára Jakọbu.
6
Kíyèsi i, àwa gbúròó rẹ̀ ni Efrata: àwa rí i nínú oko ẹgàn náà.
7
Àwa ó lọ sínú àgọ́ rẹ̀: àwa ó máa sìn níbi àpótí ìtìsẹ̀ rẹ̀
8
Olúwa, dìde sí ibi ìsinmi rẹ: ìwọ, àti àpótí agbára rẹ.
9
Kí a fi òdodo wọ àwọn àlùfáà rẹ: kí àwọn ènìyàn mímọ́ rẹ kí ó máa hó fún ayọ̀.
10
Nítorí tí Dafidi ìránṣẹ́ rẹ̀, má ṣe yí ojú ẹni òróró rẹ padà.
Settings