Òwe 7:18-23
18
Wá, jẹ́ kí a lo ìfẹ́ papọ̀ ní kíkún títí di àárọ̀; jẹ́ kí a gbádùn ara wa pẹ̀lú ìfẹ́!
19
Ọkọ ọ̀ mi ò sí nílé; ó ti lọ sí ìrìnàjò jíjìn.
20
Ó mú owó púpọ̀ lọ́wọ́ kò sì ní darí dé kí ó tó di ọ̀sán.”
21
Pẹ̀lú ọ̀rọ̀ dídùn ó sì í lọ́nà; ó tàn án jẹ pẹ̀lú ẹnu dídùn.
22
Òun sì tọ̀ ọ́ lọ lẹsẹ̀ kan náà, bí i màlúù tí ń lọ sí ibi pípa, tàbí bí àgbọ̀nrín tí ń lọ sí ibi okùn ìso.
23
Títí tí ọ̀kọ̀ fi gún un ní ẹ̀dọ̀, bí ẹyẹ ṣe ń fẹ́ wọ inú okùn, láìmọ̀ pé yóò gba ẹ̀mí òun.
Settings