Òwe 5:7
Ń ṣàfihàn ẹsẹ 7 pẹ̀lú àyíká ọ̀rọ̀ tó yí i ká.
4
Ṣùgbọ́n ní ìgbẹ̀yìn gbẹ́yín, ó korò ju òróǹró lọ, ó mú bí idà olójú méjì.
5
Ẹsẹ̀ rẹ̀ sọ̀kalẹ̀ lọ sí ọ̀nà ikú ìgbésẹ̀ rẹ̀ lọ tààrà sí ibojì òkú.
6
Kí ìwọ má ba à já ipa ọ̀nà ìyè; ọ̀nà rẹ̀ rí pálapàla, ṣùgbọ́n kò tilẹ̀ mọ́.
7
Nítorí náà, ẹ̀yin ọmọ mi, ẹ dẹtí sí mi, kí ẹ̀yin kí ó má ṣe yàgò kúrò nínú ọ̀rọ̀ tí mo sọ.
8
Rìn ní ọ̀nà tí ó jìnnà sí ti rẹ̀, má ṣe súnmọ́ ẹnu-ọ̀nà ilé rẹ̀,
9
àìṣe bẹ́ẹ̀ ìwọ yóò gbé gbogbo ọlá rẹ lé ẹlòmíràn lọ́wọ́ àti ọjọ́ ayé rẹ fún ìkà ènìyàn.
10
Kí a má ba à fi ọrọ̀ rẹ fún àjèjì ènìyàn, kí làálàá rẹ sì sọ ilé ẹlòmíràn di ọlọ́rọ̀.
Settings