Skip to content
Òwe 14:1-11

Òwe 14:1-11

1
Ọlọ́gbọ́n obìnrin kọ́ ilé e rẹ̀, ṣùgbọ́n aṣiwèrè obìnrin fi ọwọ́ ara rẹ̀ fà á lulẹ̀.
2
Ẹni tí ń rìn déédé bẹ̀rù Olúwa, ṣùgbọ́n ẹni tí ọ̀nà rẹ̀ kò tọ́ kẹ́gàn Olúwa.
3
Ọ̀rọ̀ aṣiwèrè a máa ṣokùnfà pàṣán fún ẹ̀yìn rẹ̀, ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ ètè ọlọ́gbọ́n a máa dáàbò bò ó.
4
Níbi tí kò sí ẹran, ibùjẹ ẹran a máa mọ́ tónítóní, ṣùgbọ́n, nípa agbára akọ màlúù ni ọ̀pọ̀ ìkórè ti ń wá.
5
Ẹlẹ́rìí tí ń ṣọ òtítọ́ kì í tan ni ṣùgbọ́n ẹlẹ́rìí èké a máa tú irọ́ jáde.
6
Ẹlẹ́gàn ń wá ọgbọ́n kò sì rí rárá, ṣùgbọ́n ìmọ̀ máa ń wà fún olóye.
7
Má ṣe súnmọ́ aláìgbọ́n ènìyàn, nítorí ìwọ kì yóò rí ìmọ̀ ní ètè rẹ̀.
8
Ọgbọ́n olóye ni láti ronú jinlẹ̀ nípa ọ̀nà wọn ṣùgbọ́n ìwà òmùgọ̀ aṣiwèrè ni ìtànjẹ.
9
Aláìgbọ́n ń dẹ́ṣẹ̀ nígbà tí ó yẹ kí ó ṣe àtúnṣe ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ ṣùgbọ́n láàrín àwọn olódodo ni a ti rí ojúrere.
10
Ọkàn kọ̀ọ̀kan ló mọ ẹ̀dùn ọkàn tirẹ̀ kò sì ṣí ẹnìkan tó le è bá ọkàn mìíràn pín ayọ̀ rẹ̀.
11
A ó pa ilé ènìyàn búburú run, ṣùgbọ́n àgọ́ olódodo yóò máa gbèrú sí i.
Settings

Reading Style

Typeface

Font Size 19px

Options