Skip to content
Òwe 12:15-23

Òwe 12:15-23

15
Ọ̀nà aláìgbọ́n dára lójú ara rẹ̀ ṣùgbọ́n ọlọ́gbọ́n ènìyàn a máa gba ìmọ̀ràn.
16
Aláìgbọ́n ènìyàn fi ìbínú un rẹ̀ hàn lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, ṣùgbọ́n olóye ènìyàn fojú fo ìyànjẹ.
17
Ẹni tí ó jẹ́ ajẹ́rìí òtítọ́ jẹ́rìí ohun tí ojú rẹ̀ rí ṣùgbọ́n ajẹ́rìí èké máa ń parọ́.
18
Ọ̀rọ̀ tí a kò rò jinlẹ̀ máa ń gún ni bí ọ̀kọ̀ ṣùgbọ́n ahọ́n ọlọ́gbọ́n ń mú ìwòsàn wá.
19
Ètè tí ń ṣọ òtítọ́ yóò wà láéláé ṣùgbọ́n ahọ́n tí ń parọ́ kì í tọ́jọ́.
20
Ẹ̀tàn wà nínú ọkàn àwọn tí ń pète búburú ṣùgbọ́n ayọ̀ wà fún àwọn tí ń mú kí àlàáfíà gbilẹ̀.
21
Ibi kì í ṣubú lu olódodo rárá ṣùgbọ́n ènìyàn búburú gba ìpín ìyọnu tiwọn.
22
Olúwa kórìíra ètè tí ń parọ́ ṣùgbọ́n ó ní inú dídùn sí àwọn olóòtítọ́.
23
Ènìyàn olóye fi ìmọ̀ rẹ̀ pamọ́ sínú ara rẹ̀ ṣùgbọ́n ọkàn ènìyàn búburú ń gbé ìwà òmùgọ̀ jáde.
Settings

Reading Style

Typeface

Font Size 19px

Options