Filipi 4:4-9
4
Ẹ máa yọ̀ nínú Olúwa nígbà gbogbo: mo sì tún wí pé. Ẹ máa yọ̀.
5
Ẹ jẹ́ ki ìpamọ́ra yín di mímọ́ fún gbogbo ènìyàn, Olúwa ń bẹ nítòsí.
6
Ẹ má ṣe ṣe àníyàn ohunkóhun; ṣùgbọ́n nínú ohun gbogbo, nípa àdúrà àti ẹ̀bẹ̀ pẹ̀lú ìdúpẹ́, ẹ máa fi ìbéèrè yín hàn fún Ọlọ́run.
7
Àti àlàáfíà Ọlọ́run, tí ó ju ìmòye gbogbo lọ, yóò pa ọkàn àti èrò yín mọ nínú Kristi Jesu.
8
Ní àkótán, ará, ohunkóhun tí í ṣe òtítọ́, ohunkóhun tí í ṣe ọ̀wọ̀, ohunkóhun tí í ṣe títọ́ ohunkóhun tí í ṣe mímọ́, ohunkóhun tí í ṣe fífẹ́, ohunkóhun tí ó ni ìròyìn rere, bí ìwà títọ́ kan bá wà, bí ìyìn kan bá sì wà, ẹ máa gba nǹkan wọ̀nyí rò.
9
Àwọn nǹkan tí ẹ̀yin ti kọ́, tí ẹ̀yin sì ti gbà, tí ẹ̀yin sì ti gbọ́, tí ẹ̀yin sì ti rí lọ́wọ́ mi, ẹ máa ṣe wọ́n: Ọlọ́run àlàáfíà yóò sì wà pẹ̀lú yín.
Settings