Numeri 6:14
Ń ṣàfihàn ẹsẹ 14 pẹ̀lú àyíká ọ̀rọ̀ tó yí i ká.
11
Àlùfáà yóò fi ọ̀kan rú ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ àti èkejì fún ẹbọ sísun láti fi ṣe ètùtù fún un nítorí pé ó ti ṣẹ̀ nípa wíwà níbi tí òkú ènìyàn wà. Yóò sì ya orí rẹ̀ sí mímọ́ ní ọjọ́ náà gan an.
12
Ó gbọdọ̀ ya ara rẹ̀ sọ́tọ̀ sí Olúwa fún àkókò ìyàsọ́tọ̀ rẹ̀, ó sì gbọdọ̀ mú akọ ọ̀dọ́-àgùntàn ọlọ́dún kan wá gẹ́gẹ́ bí ọrẹ ẹ̀bi. Kò sì ní í ka àwọn ọjọ́ ìyàsọ́tọ̀ rẹ̀ ti tẹ́lẹ̀ nítorí pé ó tí ba ara rẹ̀ jẹ́ ní àkókò ìyàsọ́tọ̀ rẹ̀.
13
“ ‘Èyí ni òfin fún Nasiri nígbà tí àkókò ìyàsọ́tọ̀ rẹ̀ bá pé. Wọn ó mu wá sí ẹnu-ọ̀nà àgọ́ ìpàdé.
14
Níbẹ̀ ni yóò ti mú ọrẹ wá fún Olúwa, akọ ọ̀dọ́-àgùntàn ọlọ́dún kan tí kò ní àbùkù fún ẹbọ sísun àti ẹgbọrọ-àgùntàn ọlọ́dún kan, tí kò ní àbùkù fún ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀, àgbò kan tí kò ní àbùkù fún ọrẹ àlàáfíà,
15
pẹ̀lú ọrẹ ohun jíjẹ àti ọrẹ ohun mímu, apẹ̀rẹ̀ àkàrà tí a kò fi ìwúkàrà ṣe, àkàrà tí a fi ìyẹ̀fun dáradára pò mọ́ òróró àti àkàrà fẹ́lẹ́fẹ́lẹ́ tí a fi òróró sọjọ̀ lé lórí.
16
“ ‘Àlùfáà yóò gbé gbogbo rẹ̀ wá síwájú Olúwa, yóò sì rú ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ àti ẹbọ sísun.
17
Àlùfáà yóò fi àgbò náà rú ẹbọ àlàáfíà sí Olúwa, pẹ̀lú apẹ̀rẹ̀ àkàrà tí kò ní ìwúkàrà; yóò rú ẹbọ ohun jíjẹ àti ọrẹ ohun mímu.
Settings