Numeri 5:19-24
19
Àlùfáà yóò sì mú obìnrin náà búra, yóò wí pé, “Bí ọkùnrin mìíràn kò bá bá ọ lòpọ̀, tí ó kò sì yapa, tí o kò sì di aláìmọ́ níwọ̀n ìgbà tí ó wà lábẹ́ àṣẹ ọkọ rẹ̀, a jẹ́ pé omi kíkorò tí ń mú ègún wá yìí kò ní ṣe ọ́ níbi.
20
Ṣùgbọ́n tí ìwọ bá ti yapa kúrò lọ́dọ̀ ọkọ rẹ, tí o bá ti ba ara rẹ jẹ́ nípa jíjẹ́ kí ọkùnrin tí kì í ṣe ọkọ rẹ bá ọ lòpọ̀,”
21
nígbà náà ni àlùfáà yóò mú obìnrin náà búra, yóò sọ fún obìnrin náà pé, “Kí Olúwa sọ ọ́ di ẹni ègún àti ẹni ìbáwí láàrín àwọn ènìyàn rẹ nípa mímú kí itan rẹ jẹrà, kí ikùn rẹ̀ sì wú.
22
Ǹjẹ́ kí omi yìí tí ń mú ègún wá wọ inú ara rẹ, kí ó mú ikùn rẹ̀ wú, kí ó sì mú itan rẹ̀ jẹrà dànù.” “ ‘Obìnrin náà yóò sì wí pé, “Àmín. Bẹ́ẹ̀ ni kó rí.”
23
“ ‘Nígbà náà ni àlùfáà yóò kọ ègún yìí sínú ìwé kíká, yóò sì sìn ín sínú omi kíkorò náà.
24
Àlùfáà yóò sì mú kí obìnrin náà mu omi kíkorò tí ń mú ègún wá yìí, omi náà yóò wọ inú rẹ̀ yóò sì fa ìrora kíkorò fún obìnrin náà bí ó bá jẹ̀bi.
Settings