Skip to content
Numeri 3:17-37

Numeri 3:17-37

17
Wọ̀nyí ni orúkọ àwọn ọmọ Lefi: Gerṣoni, Kohati àti Merari.
18
Wọ̀nyí ni orúkọ àwọn ọmọ Gerṣoni: Libni àti Ṣimei.
19
Àwọn ìdílé Kohati ni: Amramu, Isari, Hebroni àti Usieli.
20
Àwọn ìdílé Merari ni: Mahili àti Muṣi. Wọ̀nyí ni ìdílé Lefi gẹ́gẹ́ bí ilé baba wọn.
21
Ti Gerṣoni ni ìdílé Libni àti Ṣimei; àwọn ni ìdílé Gerṣoni.
22
Iye àwọn ọmọkùnrin tí ọjọ́ orí wọ́n jẹ́ oṣù kan ó lé, jẹ́ ẹgbàata ó lé ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀jọ (7,500).
23
Àwọn ìdílé Gerṣoni yóò pa ibùdó sí ìhà ìwọ̀-oòrùn lẹ́yìn àgọ́.
24
Olórí àwọn ìdílé Gerṣoni ni Eliasafu ọmọ Láélì.
25
Iṣẹ́ àwọn ìdílé Gerṣoni nínú àgọ́ ìpàdé ni pé àwọn yóò máa tọ́jú àgọ́, ìbòrí àgọ́, aṣọ títa ẹnu-ọ̀nà àgọ́ ìpàdé,
26
aṣọ títa ti àgbàlá, aṣọ títa ti ẹnu-ọ̀nà àgbàlá tó yí àgọ́ àti pẹpẹ ká, àwọn okùn rẹ̀ àti gbogbo ohun tó jẹ mọ́ lílò wọn.
27
Ti Kohati ní ìdílé Amramu, Isari, Hebroni àti Usieli, wọ̀nyí ni ìran Kohati.
28
Iye gbogbo ọmọkùnrin tí ọjọ́ orí wọn jẹ́ ọmọ oṣù kan ó lé jẹ́ ẹgbàá mẹ́rin ó lé ẹgbẹ̀ta (8,600), tí yóò máa ṣiṣẹ́ ní ibi mímọ́.
29
Àwọn ìdílé Kohati yóò pa ibùdó wọn sí ìhà gúúsù ní ẹ̀gbẹ́ àgọ́.
30
Olórí àwọn ìdílé Kohati ni Elisafani ọmọ Usieli.
31
Àwọn ni yóò máa tọ́jú àpótí ẹ̀rí, tábìlì, ọ̀pá fìtílà, àwọn pẹpẹ, gbogbo ohun èlò ibi mímọ́ tí à ń lò fún iṣẹ́ ìsìn, aṣọ títa àti gbogbo ohun tó jẹ mọ́ lílò wọn.
32
Eleasari ọmọ Aaroni àlùfáà ni alákòóso gbogbo àwọn olórí ìdílé Lefi. Òun ni wọ́n yàn lórí gbogbo àwọn tí yóò máa tọ́jú ibi mímọ́.
33
Ti Merari ni ìran Mahili àti Muṣi, àwọn ni ìran Merari.
34
Iye gbogbo ọmọkùnrin tí ọjọ́ orí wọ́n jẹ́ oṣù kan ó lé, èyí tí wọ́n kà jẹ́ igba mọ́kànlélọ́gbọ̀n (6,200).
35
Olórí àwọn ìdílé ìran Merari ni Ṣurieli ọmọ Abihaili. Wọn yóò pa ibùdó wọn sí ìhà àríwá àgọ́.
36
Àwọn ìran Merari ni a yàn fún títọ́jú àwọn férémù àgọ́, ọ̀pá ìdábùú rẹ̀, òpó rẹ̀, ihò òpó rẹ̀ àti gbogbo ohun èlò tó jẹ mọ́ lílò wọn.
37
Iṣẹ́ wọn tún ni títọ́jú àwọn òpó tó yí àgbàlá ká, ihò òpó rẹ̀, èèkàn àti okùn wọn.
Settings

Reading Style

Typeface

Font Size 19px

Options