Ìkànsí àti àwọn ojúṣe àwọn ìdílé Lefi
14
Nígbà náà ni Olúwa sọ fún Mose ní aginjù Sinai pé,
15
“Ka àwọn ọmọ Lefi nípa ilé baba wọn àti ìdílé wọn kí o ka gbogbo ọmọkùnrin láti ọmọ oṣù kan sókè.”
16
Mose sì kà wọ́n gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ Olúwa ti pa á láṣẹ fún un.
17
Wọ̀nyí ni orúkọ àwọn ọmọ Lefi: Gerṣoni, Kohati àti Merari.
18
Wọ̀nyí ni orúkọ àwọn ọmọ Gerṣoni: Libni àti Ṣimei.
19
Àwọn ìdílé Kohati ni: Amramu, Isari, Hebroni àti Usieli.
20
Àwọn ìdílé Merari ni: Mahili àti Muṣi. Wọ̀nyí ni ìdílé Lefi gẹ́gẹ́ bí ilé baba wọn.
Settings