Numeri 26:28-37
28
Àwọn ọmọ Josẹfu gẹ́gẹ́ bí ìdílé wọn; Manase àti Efraimu.
29
Àwọn ọmọ Manase: ti Makiri, ìdílé Makiri (Makiri sì bí Gileadi); ti Gileadi, ìdílé àwọn ọmọ Gileadi.
30
Wọ̀nyí ni àwọn ọmọ Gileadi: ti Ieseri, ìdílé Ieseri; ti Heleki, ìdílé Heleki
31
àti ti Asrieli, ìdílé Asrieli; àti ti Ṣekemu, ìdílé Ṣekemu;
32
àti Ṣemida, ìdílé àwọn ọmọ Ṣemida; àti ti Heferi, ìdílé àwọn ọmọ Heferi.
33
(Selofehadi ọmọ Heferi kò sì ni ọmọkùnrin, bí kò ṣe ọmọbìnrin; orúkọ àwọn ọmọbìnrin ni Mahila, Noa, àti Hogla, Milka àti Tirsa).
34
Wọ̀nyí ni ìdílé Manase tí iye wọn sì jẹ́ ẹgbàá mẹ́rìndínlọ́gbọ̀n ó lé lẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rin (52,700).
35
Wọ̀nyí ni àwọn ọmọ Efraimu gẹ́gẹ́ bí ìdílé wọn: láti ọ̀dọ̀ Ṣutelahi, ìdílé àwọn ọmọ Ṣutelahi; ti Bekeri, ìdílé àwọn ọmọ Bekeri; ti Tahani, ìdílé àwọn ọmọ Tahani.
36
Wọ̀nyí ni àwọn ọmọ Ṣutelahi: ti Erani, ìdílé àwọn ọmọ Erani.
37
Wọ̀nyí ni ìdílé àwọn ọmọ Efraimu, àwọn tí a kà nínú wọn sì jẹ́ ẹgbàá mẹ́rìndínlógún ó lé lẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta (32,500). Wọ̀nyí ni àwọn ọmọ Josẹfu gẹ́gẹ́ bí ìdílé wọn.
Settings