Numeri 21:21-32
21
Israẹli rán oníṣẹ́ láti sọ fún Sihoni ọba àwọn ará Amori wí pé,
22
“Jẹ́ kí a kọjá ní orílẹ̀-èdè rẹ. A kò ní kọjá sí inú oko pápá tàbí ọgbà àjàrà àbí mu omi láti inú kànga. A máa gba òpópónà náà ti ọba títí tí a ó fi la ilẹ̀ rẹ kọjá.”
23
Ṣùgbọ́n Sihoni kò ní jẹ́ kí àwọn Israẹli kọjá ní ilẹ̀ wọn. Ó pe àwọn ọmọ-ogun rẹ̀ jọ wọ́n sì wọ́de ogun lọ sí aginjù nítorí àwọn ọmọ Israẹli. Nígbà tí ó dé Jahasi, ó bá àwọn ọmọ Israẹli jà.
24
Àmọ́, Israẹli ṣẹ́gun, wọn fi ojú idà pa wọ́n, wọ́n sì gba ilẹ̀ láti ọwọ́ Arnoni lọ dé Jabbok, títí tí ó fi dé ilẹ̀ àwọn ará Ammoni, nítorí pé ààlà wọn jẹ́ olódi.
25
Israẹli sì gba gbogbo ìlú Amori wọ́n sì ń gbé ibẹ̀ pẹ̀lú Heṣboni, àti gbogbo ibùgbé ìlú tó yí i ká.
26
Heṣboni ni ìlú Sihoni ọba àwọn ará Amori, ẹni tí ó bá ọba Moabu ti tẹ́lẹ̀ jà tí ó sì gba gbogbo ilẹ̀ rẹ̀ ní ọwọ́ rẹ̀ títí dé Arnoni.
27
Ìdí nìyìí tí akọrin sọ wí pé, “Wá sí Heṣboni kí ẹ jẹ́ kí a tún un kọ́; jẹ́ kí ìlú Sihoni padà bọ̀ sípò.
28
“Iná jáde láti Heṣboni, ọ̀wọ́-iná láti Sihoni. Ó jó Ari àti Moabu run, àti ìlú àwọn olùgbé ibi gíga Arnoni.
29
Ègbé ní fún ọ, ìwọ Moabu! Ẹ ti parun, ẹ̀yin ènìyàn Kemoṣi! Ó ti fi ọmọ rẹ̀ ọkùnrin sílẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ìsáǹsá àti ọmọ rẹ̀ obìnrin gẹ́gẹ́ bí ìgbèkùn fún Sihoni ọba àwọn Amori.
30
“Ṣùgbọ́n àti bì wọ́n ṣubú; a ti pa ìjẹgàba Heṣboni run, a pa wọ́n run títí dé Diboni. A sì ti bì wọ́n lulẹ̀ títí dé Nofa, tí ó sì fi dé Medeba.”
31
Nígbà náà ni àwọn ọmọ Israẹli sì ń gbé ní ilẹ̀ Amori.
32
Lẹ́yìn ìgbà tí Mose rán ayọ́lẹ̀wò lọ sí Jaseri, àwọn ọmọ Israẹli sì gba àwọn agbègbè tó yí wọn ká wọ́n sì lé àwọn Amori tó wà níbẹ̀ jáde.
Settings