Nahumu 3:12-19
12
Gbogbo ilé ìṣọ́ agbára rẹ yóò dàbí igi ọ̀pọ̀tọ́ pẹ̀lú àkọ́pọ́n èso wọn; nígbà tí wọ́n bá ń gbọ̀n wọ́n, ọ̀pọ̀tọ́ yóò sì bọ́ sí ẹnu àwọn ọ̀jẹun.
13
Kíyèsi gbogbo àwọn jagunjagun! Obìnrin ni gbogbo wọn. Ojú ibodè rẹ ní a ó ṣí sílẹ̀ gbagada, fún àwọn ọ̀tá rẹ; iná yóò jó ọ̀pá ìdábùú ìlẹ̀kùn ibodè rẹ.
14
Pọn omi nítorí ìhámọ́, mú ilé ìṣọ́ rẹ lágbára sí i wọ inú amọ̀ kí o sì tẹ erùpẹ̀, kí ó sì tún ibi tí a ti ń sun bíríkì-amọ̀ ṣe kí ó le.
15
Níbẹ̀ ni iná yóò ti jó ọ́ run; idà yóò sì ké ọ kúrò, yóò sì jẹ ọ́ bí i kòkòrò, yóò sì sọ ara rẹ̀ di púpọ̀ bí i tata, àní, di púpọ̀ bí eṣú!
16
Ìwọ ti sọ àwọn oníṣòwò rẹ di púpọ̀ títí wọn yóò fi pọ̀ ju ìràwọ̀ ojú ọ̀run lọ, ṣùgbọ́n bi eṣú ni wọn yóò sọ ilẹ̀ náà di ahoro, wọn yóò sì fò lọ.
17
Àwọn aládé rẹ̀ dàbí eṣú, àwọn ọ̀gágun rẹ dàbí ẹlẹ́ǹgà ńlá, èyí tí ń dó sínú ọgbà ni ọjọ́ òtútù, ṣùgbọ́n nígbà tí oòrùn jáde, wọ́n sálọ, ẹnìkan kò sì mọ ibi tí wọ́n gbé wà.
18
Ìwọ ọba Asiria, àwọn olùṣọ́-àgùntàn rẹ̀ ń tòògbé; àwọn ọlọ́lá rẹ dùbúlẹ̀ láti sinmi. Àwọn ènìyàn rẹ fọ́nká lórí àwọn òkè ńlá, tí ẹnikẹ́ni kò sì kó wọn jọ.
19
Kò sì sí ohun tí ó lè wo ọgbẹ́ ẹ̀ rẹ sàn; ọgbẹ́ rẹ kún fún ìrora, Gbogbo ẹni tí ó bá sì gbọ́ ìròyìn rẹ yóò pàtẹ́wọ́ lé ọ lórí, nítorí ta ni kò ní pín nínú ìwà búburú rẹ ti kò ti lópin.
Settings