Nahumu 1:1
Ń ṣàfihàn ẹsẹ 1 pẹ̀lú àyíká ọ̀rọ̀ tó yí i ká.
1
Ọ̀rọ̀-ìmọ̀ nípa Ninefe. Ìwé ìran Nahumu ará Elkoṣi.
2
Ọlọ́run ń jẹ owú, ó sì ń gbẹ̀san, Olúwa ń gbẹ̀san, ó sì kún fún ìbínú. Olúwa ń gbẹ̀san lára àwọn ọ̀tá rẹ̀. Ìbínú rẹ̀ kò sì yí padà lórí àwọn ọ̀tá rẹ̀.
3
Olúwa lọ́ra láti bínú, ó sì tóbi ní agbára; Olúwa kì yóò fi àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ sílẹ̀ láìjìyà. Ọ̀nà rẹ̀ wà nínú afẹ́fẹ́ àti nínú ìjì, ìkùùkuu sánmọ̀ sì ni eruku ẹsẹ̀ rẹ̀.
4
Ó bá òkun wí, ó sì mú kí ó gbẹ; Ó sìsọ gbogbo odò di gbígbẹ. Baṣani àti Karmeli sì rọ. Ìtànná Lebanoni sì rẹ̀ sílẹ̀.
Settings