Mika 7:1-6
1
Ègbé ni fún mi! Nítorí èmi sì dàbí ẹni tí ń kó èso ẹ̀ẹ̀rùn jọ, ìpèsè ọgbà àjàrà; kò sì ṣí odidi àjàrà kankan láti jẹ, kò sì ṣí àkọ́so ọ̀pọ̀tọ́ nítorí tí ebi ń pa mí.
2
Àwọn olódodo sì ti kúrò ní ilẹ̀ náà, kò sì ṣí ẹnìkan tí ó ṣẹ́kù tí ó jọ olóòtítọ́; gbogbo wọn sì ń purọ́ ní dídúró nítorí ìtàjẹ̀ sílẹ̀, olúkúlùkù wọ́n sì ń fi àwọ̀n de arákùnrin rẹ̀.
3
Ọwọ́ wọn méjèèjì ti múra tán láti ṣe búburú; àwọn alákòóso ń béèrè fún ẹ̀bùn, àwọn onídàájọ́ sì ń gba owó àbẹ̀tẹ́lẹ̀ alágbára sì ń pàṣẹ ohun tí wọ́n fẹ́, gbogbo wọn sì jùmọ̀ ń dìtẹ̀.
4
Ẹni tí ó sàn jùlọ nínú wọn sì dàbí ẹ̀gún, ẹni tí ó jẹ́ olódodo jùlọ burú ju ẹ̀gún ọgbà lọ. Ọjọ́ àwọn olùṣọ́ rẹ̀ ti dé, àti ọjọ́ tí Ọlọ́run bẹ̀ ọ́ wò. Nísinsin yìí ní àkókò ìdààmú wọn.
5
Ẹ má ṣe gba ọ̀rẹ́ kan gbọ́; ẹ má sì ṣe gbẹ́kẹ̀lé amọ̀nà kankan. Pa ìlẹ̀kùn ẹnu rẹ fún ẹni tí ó sùn ní oókan àyà rẹ.
6
Nítorí tí ọmọkùnrin kò bọ̀wọ̀ fún baba rẹ̀, ọmọbìnrin sì dìde sí ìyá rẹ̀, aya ọmọ sí ìyá ọkọ rẹ̀, ọ̀tá olúkúlùkù ni àwọn ará ilé rẹ̀.
Settings