Mika 2:6-11
6
“Ẹ má ṣe sọtẹ́lẹ̀,” ni àwọn wòlíì wọn wí. “Ẹ má ṣe sọtẹ́lẹ̀ nípa nǹkan wọ̀nyí; kí ìtìjú má ṣe le bá wa.”
7
Ṣé kí á sọ ọ́, ìwọ ilé Jakọbu: “Ǹjẹ́ ẹ̀mí Olúwa ha ń bínú bí? Ǹjẹ́ iṣẹ́ rẹ ha nìwọ̀nyí?” “Ǹjẹ́ ọ̀rọ̀ mi kò ha ń ṣe rere fún ẹni tí ń rìn déédé bí?
8
Láìpẹ́ àwọn ènìyàn mi dìde bí ọ̀tá sí mi. Ìwọ bọ́ aṣọ ọlọ́rọ̀ kúrò lára àwọn tí ń kọjá lọ ní àìléwu, bí àwọn ẹni tí ó padà bọ̀ láti ojú ogun.
9
Ẹ̀yin sì lé obìnrin àwọn ènìyàn mi kúrò nínú ilé ayọ̀ wọn, ẹ̀yin sì ti gba ògo mi, kúrò lọ́wọ́ àwọn ọmọ wọn láéláé.
10
Ẹ dìde, kí ẹ sì máa lọ! Nítorí èyí kì í ṣe ibi ìsinmi yín, nítorí tí a ti sọ ọ́ di àìmọ́ yóò pa yín run, àní ìparun kíkorò.
11
Tí òpùrọ́ àti ẹlẹ́tàn bá wà tí wọ́n sì wí pé, ‘Èmi yóò sọtẹ́lẹ̀ fún ọ nípa ọ̀pọ̀lọpọ̀ wáìnì àti ọtí líle,’ òun ni yóò tilẹ̀ ṣe wòlíì àwọn ènìyàn wọ̀nyí!
Settings