Matiu 3:1-6
1
Ní ọjọ́ wọ̀n-ọn-nì, Johanu onítẹ̀bọmi wá, ó ń wàásù ní aginjù Judea.
2
Ó ń wí pé, “Ẹ ronúpìwàdà, nítorí ìjọba ọ̀run kù sí dẹ̀dẹ̀.”
3
Èyí ni ẹni náà ti wòlíì Isaiah sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ pé, “Ohùn ẹni ti ń kígbe ní ijù, ‘Ẹ tún ọ̀nà Olúwa ṣe, ẹ ṣe ojú ọ̀nà rẹ̀ kí ó tọ́.’ ”
4
Aṣọ Johanu náà sì jẹ́ ti irun ìbákasẹ, ó sì di àmùrè awọ sí ẹ̀gbẹ́ rẹ̀. Eṣú àti oyin ìgàn sì ni oúnjẹ rẹ̀.
5
Àwọn ènìyàn jáde lọ sọ́dọ̀ rẹ̀ láti Jerusalẹmu àti gbogbo Judea àti àwọn ènìyàn láti gbogbo ìhà Jordani.
6
Wọ́n ń jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ wọn, a sì ń bamitiisi wọn ní ọ̀dọ̀ rẹ̀ ní odò Jordani.
Settings