Matiu 13:18-23
18
“Nítorí náà, ẹ fi etí sí ohun tí òwe afúnrúgbìn túmọ̀ sí,
19
nígbà tí ẹnikẹ́ni bá gbọ́ ọ̀rọ̀ nípa ìjọba ọ̀run ṣùgbọ́n tí kò yé e, lẹ́yìn náà èṣù á wá, a sì gba èyí tí a fún sí ọkàn rẹ̀ kúrò. Èyí ni irúgbìn ti a fún sí ẹ̀bá ọ̀nà.
20
Ẹni tí ó sì gba irúgbìn tí ó bọ́ sí ilẹ̀ orí àpáta, ni ẹni tí ó gbọ́ ọ̀rọ̀ náà, lọ́gán, ó sì fi ayọ̀ gba ọ̀rọ̀ náà.
21
Ṣùgbọ́n nítorí kò ní gbòǹgbò, ó wà fún ìgbà díẹ̀; nígbà tí wàhálà àti inúnibíni bá dìde nítorí ọ̀rọ̀ náà ní ojú kan náà yóò sì kọsẹ̀.
22
Ẹni tí ó si gba irúgbìn tí ó bọ́ sí àárín ẹ̀gún ni ẹni tí ó gbọ́ ọ̀rọ̀ náà, ṣùgbọ́n àwọn àníyàn ayé yìí, ìtànjẹ, ọrọ̀ sì fún ọ̀rọ̀ náà pa, ọ̀rọ̀ náà kò so èso nínú rẹ̀.
23
Ṣùgbọ́n ẹni tí ó gba irúgbìn tí ó bọ́ sí orí ilẹ̀ rere ni ẹni tí ó gbọ́ ọ̀rọ̀ náà, tí ó sì yé e; òun sì so èso òmíràn ọgọ́rọ̀ọ̀rùn, òmíràn ọgọ́tọ̀ọ̀ta, òmíràn ọgbọọgbọ̀n.”
Settings