Marku 4:3-14
3
“Ẹ fi etí sílẹ̀! Ní ọjọ́ kan, afúnrúgbìn kan jáde lọ láti lọ fúnrúgbìn rẹ̀.
4
Bí ó ti ń fúnrúgbìn, díẹ̀ bọ́ sí ẹ̀bá ọ̀nà, àwọn ẹyẹ sì wá, wọ́n sì ṣà á jẹ.
5
Díẹ̀ bọ́ sórí ilẹ̀ àpáta, níbi tí erùpẹ̀ ko sí púpọ̀. Láìpẹ́ ọjọ́, ó hu jáde.
6
Ṣùgbọ́n nígbà tí oòrùn mú gangan, ó jóná, nítorí tí kò ní gbòǹgbò, ó gbẹ.
7
Àwọn irúgbìn mìíràn sì bọ́ sáàrín ẹ̀gún, nígbà tí ẹ̀gún sì dàgbàsókè, ó fún wọn pa, tó bẹ́ẹ̀ tí àwọn irúgbìn náà kò le so èso.
8
Ṣùgbọ́n òmíràn bọ́ sí ilẹ̀ ọlọ́ràá, o sì so èso lọ́pọ̀lọ́pọ̀, òmíràn ọgbọọgbọ̀n, òmíràn ọgọọgọ́ta, àti òmíràn ọgọọgọ́rùn-ún.”
9
Jesu sì wí pé, “Ẹni tí ó bá ní etí láti fi gbọ́, kí ó gbọ́.”
10
Nígbà tí ó ku òun nìkan pẹ̀lú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn méjìlá àti àwọn mìíràn, wọ́n bi í léèrè wí pé, “Kí ni ìtumọ̀ òwe rẹ̀?”
11
Ó sì dá wọn lóhùn pé, “Ẹ̀yin ni a gbà láààyè láti mọ ohun ìjìnlẹ̀ nípa ìjọba Ọlọ́run. Èyí tí ó pamọ́ sí àwọn tí ó wà lẹ́yìn agbo ìjọba náà.
12
Bí ó tilẹ̀ jẹ́ wí pé, “ ‘wọn yóò rí i, wọn yóò sì gbọ́, kì yóò yé wọn, bẹ́ẹ̀ ni wọn kì yóò sì yípadà sí Ọlọ́run. Tàbí kí a dárí ẹ̀ṣẹ̀ jì wọ́n!’ ”
13
Ṣùgbọ́n Jesu wí fún wọn pé, “Bí òwe tí ó rọrùn yìí kò bá yé e yín? Báwo ni ẹ̀yin yóò ṣe mọ ìtumọ̀ àwọn mìíràn tí mo ń sọ fún un yín?
14
Afúnrúgbìn ń fúnrúgbìn ọ̀rọ̀ náà.
Settings