Marku 13:3
Ń ṣàfihàn ẹsẹ 3 pẹ̀lú àyíká ọ̀rọ̀ tó yí i ká.
1
Bí Jesu ti ń jáde láti inú tẹmpili ní ọjọ́ náà, ọ̀kan nínú ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ sọ fún un pé, “Olùkọ́, wo ilé ńlá tí ó dára wọ̀nyí. Sì wo òkúta tí a ṣe lọ́ṣọ̀ọ́ lára àwọn ògiri ilé náà.”
2
Jesu dáhùn pé, “Ìwọ rí ilé ńlá wọ̀nyí? Kì yóò sí òkúta kan tí a ó fi sílẹ̀ lórí èkejì tí a kì yóò wó lulẹ̀.”
3
Bí Jesu si ti jókòó lórí òkè olifi tí ó kọjú sí tẹmpili, Peteru, Jakọbu, Johanu àti Anderu wà pẹ̀lú rẹ̀ níbẹ̀, wọ́n bi í léèrè ni ìkọ̀kọ̀ pé,
4
“Sọ fún wa, nígbà wo ni nǹkan wọ̀nyí yóò ṣẹlẹ̀ sí tẹmpili náà? Kí ni yóò sì jẹ́ àmì nígbà tí gbogbo nǹkan wọ̀nyí yóò ṣẹ?”
5
Jesu kìlọ̀ fún wọn pé, “Ẹ má ṣe jẹ́ kí ẹnikẹ́ni tàn yín.
6
Nítorí pé ọ̀pọ̀lọpọ̀ yóò wá ní orúkọ mi, wọn yóò wí pé, ‘Èmi ni Kristi,’ wọn yóò tan ọ̀pọ̀ ènìyàn jẹ.
Settings