41
Ó sì wí fún wọn pé, “Èéṣe tí wọ́n fi ń wí pé, ọmọ Dafidi ni Kristi?
42
Dafidi tìkára rẹ̀ sì wí nínú ìwé Saamu pé: “ ‘Olúwa sọ fún Olúwa mi pé: “Ìwọ jókòó ní ọwọ́ ọ̀tún mi
43
títí èmi ó fi sọ àwọn ọ̀tá rẹ di àpótí ìtìsẹ̀ rẹ.” ’
44
Ǹjẹ́ bí Dafidi bá pè é ní ‘Olúwa.’ Òun ha sì ti ṣe jẹ́ ọmọ rẹ̀?”