Skip to content
Luku 18:32-43

Luku 18:32-43

32
Nítorí tí a ó fi lé àwọn aláìkọlà lọ́wọ́, a ó fi ṣe ẹlẹ́yà, a ó sì fi ṣe ẹ̀sín, a ó sì tutọ́ sí i lára.
33
Wọn ó sì nà án, wọn ó sì pa á, ní ọjọ́ kẹta yóò sì jíǹde.”
34
Ọ̀kan nínú nǹkan wọ̀nyí kò sì yé wọn, ọ̀rọ̀ yìí sì pamọ́ fún wọn, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò sì mọ ohun tí a wí.
35
Bí ó ti súnmọ́ Jeriko, afọ́jú kan jókòó lẹ́bàá ọ̀nà ó ń ṣagbe.
36
Nígbà tí ó gbọ́ tí ọ̀pọ̀ ń kọjá lọ, ó béèrè pé, kín ni ìtumọ̀ èyí.
37
Wọ́n sì wí fún un pé, “Jesu ti Nasareti ni ó ń kọjá lọ.”
38
Ó sì kígbe pé, “Jesu, ìwọ ọmọ Dafidi, ṣàánú fún mi!”
39
Àwọn tí ń lọ níwájú bá a wí, pé, kí ó pa ẹnu rẹ̀ mọ́, ṣùgbọ́n òun sì kígbe sókè sí í pé, “Ìwọ Ọmọ Dafidi, ṣàánú fún mi!”
40
Jesu sì dúró, ó ní, kí á mú un tọ òun wá nígbà tí ó sì súnmọ́ ọn, ó bi í
41
wí pé, “Kí ni ìwọ ń fẹ́ kí èmi ṣe fún ọ?” Ó sì wí pé, “Olúwa jẹ́ kí èmi ríran.”
42
Jesu sì wí fún un pé, “Ríran; ìgbàgbọ́ rẹ mú ọ láradá.”
43
Lójúkan náà ó sì ríran, ó sì ń tọ̀ ọ́ lẹ́yìn, ó sì ń yin Ọlọ́run lógo àti gbogbo ènìyàn nígbà tí wọ́n rí i, wọ́n fi ìyìn fún Ọlọ́run.
Settings

Reading style

Typeface

Font size 19px

Reading width 75 chars

Options