Skip to content
Luku 18:1-8

Luku 18:1-8

1
Ó sì pa òwe kan fún wọn láti fi yé wọn pe, ó yẹ kí a máa gbàdúrà nígbà gbogbo, kí a má sì ṣàárẹ̀.
2
Wí pé, “Onídàájọ́ kan wà ní ìlú kan, tí kò bẹ̀rù Ọlọ́run, tí kò sì ṣe ojúsàájú ènìyàn.
3
Opó kan sì wà ní ìlú náà, ó sì ń tọ̀ ọ́ wá, wí pé, ‘Gbẹ̀san mi lára ọ̀tá mi!’
4
“Lákọ̀ọ́kọ́ kò dá a lóhùn, ṣùgbọ́n níkẹyìn ó wí nínú ara rẹ̀ pé, ‘Bí èmi kò tilẹ̀ bẹ̀rù Ọlọ́run, tí èmi kò sì ṣe ojúsàájú ènìyàn,
5
Ṣùgbọ́n nítorí tí opó yìí ń yọ mí lẹ́nu, èmi ó gbẹ̀san rẹ̀, kí ó má ba à fi wíwá rẹ̀ nígbàkígbà dá mi lágara.’ ”
6
Olúwa sì wí pé, “Ẹ gbọ́ bí aláìṣòótọ́ onídàájọ́ ti wí!
7
Ọlọ́run kì yóò ha sì gbẹ̀san àwọn àyànfẹ́ rẹ̀, tí ń fi ọ̀sán àti òru kígbe pè é, tí ó sì mú sùúrù fún wọn?
8
Mo wí fún yín, yóò gbẹ̀san wọn kánkán! Ṣùgbọ́n nígbà tí Ọmọ Ènìyàn bá dé yóò ha rí ìgbàgbọ́ ní ayé bí?”
Settings

Reading Style

Typeface

Font Size 19px

Options